YORÙBÁ DÙÚN KÀÁÁÁ
A - Alaafia ni fun o.
B - Buburu kan ki yo o subu lu o.
D - Dugbedugbe ibanuje ko ni ja le o l'ori.
E - Ebi o ni pa o nibi ti odun yi ku si.
E - Ekun, ose ko ni je tire.
F - Funfun aye re ko ni d'ibaje.
G - Gunnugun ki ku l'ewe, wa d'agba d'arugbo.
GB - Gbogbo idawole re a y'ori si rere.
H - Hausa, Yoruba, Ibo, gbogbo eya ati eniyan kaakiri agbaye ni yo koju si o se o loore.
I - Iwaju, iwaju l'opa ebiti re yo ma re si.
J - Jijade re, wiwole re, o o nik'agbako.
K - Kukuru abi giga, osi ati ise ko ni je tire.
L - Loniloni wa r'aanu gba.
M- Monamona ati ara Olorun yoo tu awon ota re ka.
N - Naira, Euro, Dollar,Pound, Yen, Yuan, gbogbo owo ati oro kaakiri agbaye pelu omo alalubarika ati alaafia yoo mu o l'ore, won o si fi ile re se ibugbe.
O - Ojurere ati aanu yoo ma to o leyin ni ojo aye re gbogbo.
O - Ojo ola re a dara.
P - Panpe aye o ni mu o t'omotomo.
R - Rere ni agogo aye re o ma lu n'igba gbogbo.
S - Suuru pelu itelorun ninu oro at'alaafia yoo ba o kale.
S - Sugbon ati abawon aye re ti poora loni.
T - T'omotomo, t'ebitebi, t'iletile o ni d'ero eyin.
U - "U" kii s'awati lede Ijesha; a o ni fi o s'awati laarin awon eniyan. Ulosiwaju (ilosiwaju), use rere, ati ubukun (ibunkun) yio je tire.
W - Wa ri ba ti se, wa r'ona gbe gba.
Y - Yara ibukun, ire, ati ayo ailopin loo ma ba e gbe titi ojo aye re......
AMIN L'ASE EDUMARE. Iwo naa fi ranse si awon ololufe re. Be e si ni o le fi ranse si emi naa ti moba wa lara awon ololufe re .
No comments:
Post a Comment